Jump to content

Ìkòròdú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìkòròdú
Ìlú
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ìkòròdú jé òkan lára àwon ìlú tí ó tóbi jùlọ,tí ó sí tún n dàgbà ní ìpínlẹ̀ Èkó(Lagos) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìkòròdú wà ní apá àríwá- ìlàòrùn ìlú Èkó,o sí wà láàrin adágún omi(Lagos Lagoon)ni ìpínlẹ̀ èkó ati ìpínlẹ̀ Ògùn.Ti awọn olùgbé ibè sì ju ẹgbẹ ẹgbẹrun eniyan lọ. Ìkòròdú sì wà ní ipò Kejìlá nínú ìlú tí ótóbi jù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Níwọ̀n ìgbà tí ó ń dàgbà ní ìyára 5.26% ní ọdọdún, a ṣe ìṣẹ̀dá pé yóò dé 1.7 mílíọ̀nù olùgbé ní ọdún 2035.Ó jẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ to tóbi jùlọ kejì ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọn abínibí tí wọ́n kọ́kọ́ gbé ní Ìkọ́rọ̀dú.

Ikorodu_l'oga_won

Ikorodu_road_axis

Ikorodu-Shagamu_road

Ayé àti ọ̀rọ̀ ajé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

O wa ni ibuso kilomita metadinlogoji si àríwá ìlú Èkó, Ikorodu pa ààlà pẹ̀lú gúúsù omi adagun Eko (Lagos Lagoon) ni apá àríwá opa ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ògún, to sì tún pa ààlà ní ìlà oòrùn pẹ̀lú Agbowa-Ikosi to jẹ ilu kan ni ilu Epe ti o jẹ eka ìpínlẹ̀ Èkó. . Ìlú náà ti dàgbàsókè dáa dáa ní bi ogoji ọdún sẹ́yìn tí a sì tún pín in sí àwọn agbègbè keekeeke ni bi ọna meridinlogun sí metadinlogun. Àwọn ilé iṣẹ́ pàtàkì ní ìlú náà ni ilé iṣẹ́ ìṣòwò, iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ilé iṣẹ́ ṣíṣe ohun kan jáde. Èdè Ijebu ni ede to gba ju gba ja ní ìkòròdú.

Àwọn ìlú tó gbajúmọ̀ tó wà nítòsí ni Imota, Isiu, Liadi, Egbin, Ijede, Ibeshe, Igbogbo àti Bayeku, gbogbo awọn ilu wọnyi ló ní ìgbìmọ̀ ìdàgbàsókè ìbílẹ̀ àti adari wọn gẹgẹ bi ọba. Lapapọ gbogbo awọn agbegbe yii jẹ eka Ìkòròdú.

Ẹ̀ka Ikorodu ní àpapò niilé iṣẹ́ ńlá kan tí ó ko ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé iṣẹ́ sínú. Ìlú Ikorodu fúnra rẹ̀ jẹ́ ìlú tí ọ ko opo eka ile-iṣẹ sínú gẹ́gẹ́ bí ilé ìfowópamọ́ Nàìjíríà tí a ti dá sílẹ̀.

ikorodu ní ilu ti o n ni ìdàgbàsókè julọ nínú gbogbo ilu Eko lapapọ, bẹ na sí ní gbogbo awọn ara Ìkòròdú yii gbogbo agbègbè ìlú àti abúlé to jẹ ifanimọra yi ka gbogbo ilu Eko.

Ní ọdún 2003, a pín àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ikorodu tí ó wà tẹ́lẹ̀ fún ètò ìṣàkóso sí àwọn agbègbèìgbìmọ̀ ìdàgbàsókè. Àwọn ẹ̀ka ìṣàkóso ìpele ìsàlẹ̀ náà wá jẹ́ LCDA márùn-ún àti LG kan báyìí: Imota, Igbogbo/Bayeku, Ijede, Ìpínlẹ̀ Àríwá Ikorodu, Ìwọ̀-oòrùn Ikorodu, Ikorodu (Ìpínlẹ̀). [1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Empty citation (help)